NaijaRC / yor /train.csv
aremuadeolajr's picture
Upload 5 files
879560b verified
raw
history blame
65.1 kB
year,story_id,story,question,options_A,options_B,options_C,options_D,Answer
2018,30,"Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.
Bí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.",Ohun tí ó mú ẹ̀rù Ṣàngó ba àwọn ará ìlú ni pé ó,fẹ́ ìyàwó mẹ́ta,jẹ́ Ọba Ọ̀yọ́,máa ń yọ iná lẹ́nu,jẹ́ ọmọ Tápà,C
2018,30,"Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.
Bí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.",[MASK] ni ìyàwó tí Ṣàngó fẹ́ràn jù,Ọbà,Ọya,Ọ̀ṣun,Torosi,B
2018,30,"Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.
Bí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.",Tìmì Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì,mú inú Ṣàngó bàjẹ́,di odò,ń yọ iná lẹ́nú,fi ọ̀rọ̀ lọ ìyàwó,A
2018,30,"Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.
Bí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.",Orúkọ ìyá Sangó ni,Ọ̀ṣun,Eléǹpe,Ọya,Torosi,D
2018,30,"Ìtan àbáláyé sọ pé Ọba ni Ṣàngó lóde Ọ̀yọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ọmọ ìlú Tápà ti Elérìpe ni Torosi ìyá rẹ̀. Àwọn ìyàwó mẹ́tẹ́ẹ̀ta tí Ṣàngó fẹ́ ni wọ́n di odò lẹ́yìn ikú wọn: Ọyá bínú di odò Ọya; Ọbà di odò Ọbà tí ó la Ìwó kọjá; Ọ̀ṣún sì di odò Ọ̀ṣun tí ó la Òṣogbo kọjá. Alágbára ni Ṣàngó, ó láyà, ó sì lóògùn débi pé ó máa ń yọná lẹ́nu bí inú bá ń bí i. Èyí mú kí ẹ̀ru rẹ̀ máa ba tẹrú-tọmọ lásìkò náà.
Bí Ṣàngó ṣe dẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ lóde Ọ̀yọ́ tó, Tìmí Àgbàlé àti Gbòńkáà Ẹ̀bìrì tí wọ́n jẹ́ olórí jagunjagun Ọ̀yọ́ nígbà náà kìí bẹ̀rù rẹ̀. Èyí kò sì jẹ́ kí inú Ṣàngó dùn rárá. Ó fọ̀rọ̀ náà lọ Ọya tí ó jẹ́ ààyò rẹ̀ létí. Ọyá sì gbàá nímọ̀ràn láti wá ọ̀nà ti yóò fi yẹjú àwọn méjéèjì.",ìmọ̀ràn tí a fún Ṣàngó ni pé kí ó,pa àwọn jagunjagun,fa ojú àwọn jagunjagun mọ́ra,dín inú bíbí rẹ̀ ku,sọ́ra fún àwọn ìyàwó rẹ̀,A
2018,31,"Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.
Akintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.",[MASK] ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ ède Nàìjíríà?,Olúwaṣeun,Akíntọ̀mídé,Adétutù,Abímbọ́lá,D
2018,31,"Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.
Akintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.",Àkọ́bí ìdílé yìí ni ó di,onímọ̀-ẹ̀rọ,nọ́ọ̀sì,oníṣègùn,tísà,A
2018,31,"Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.
Akintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.",tiraka’ nínú àyọkà yìí túmọ̀ sí,rin ìrìnàjò,fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run,gbìyànjú,ra mọ́tò,C
2018,31,"Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.
Akintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.",Ohun tí ó jẹ Adéagbo lógún ni,iṣẹ́ ìṣègùn,iṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ,ẹ̀kọ́ ọmọ,ìlú òyìnbó,C
2018,31,"Ọjọ́ mánigbàgbé, ọjọ́ ayọ̀, lọjọ́ tí Adétutù gbé Adéagbo àti Ajíbíkẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ lọ sí ìlú òyìnbó. Àwọn méjéèjì sì fọpẹ́ fún Ọlọ́run pé àwọ́n ti ipasẹ̀ ọmọ là. Wọn kò bá ọlá nílé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọ́n jẹ wọ́n lógún. Wọ́n tiraka láti rán àwọn ọmọ wọn nílé-ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọ náà sì kàwé yanjú.
Akintọ̀mídé, àkọ́bí wọn di ọ̀gá onímọ̀-ẹ̀rọ. Adétutù gba oyè ìmò-ìjìnlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀gùn. Olúwaṣeun di ọ̀mọ̀wé nínú iṣẹ́ olùkọ́ni. Abímbọ́lá, àbíkẹ́yìn wọ́n yan iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láàyò. Òun nìkan ni ó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn yòókù sì fi òkè-òkun ṣe ibùgbé. Bí Adéagbó àti Ajíbíkẹ̀ẹ́, ìyàwó rẹ̀ ẹe padà sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ilé tí Abímbọ́lá kọ́ fún wọn ni wọ́n dé sí. Mọ́tò ọ̀bọ̀kún ọlọ́yẹ́ tí Olúwaṣeún rà fún wọn ni ó wá gbé wọn ní pápákọ̀ òfurufú.",Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Ọjọ́ mánigbàgbé,Oúnjẹ ọmọ,Adéagbo bàbá Nọ́ọ̀sì,Ìrìnàjò Adéagbo sí ìlú òyìnbó,B
2019,32,"""Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!"" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.
Láì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.",Ta ló máa ń kọrin fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé ẹ̀kọ́ dára?,Ẹ̀gbọ́n wọn,Òbí wọn,Ọ̀rẹ́ wọn,Tísà wọn,D
2019,32,"""Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!"" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.
Láì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.",Ẹ̀gbọ́n Tèmiladé ni,Jídé,Kọ́lájọ,Kúnlé,Ṣeun,A
2019,32,"""Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!"" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.
Láì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.",Kí ni Tèmiladé kábàámọ̀ lé lórí?,ìṣẹ̀lẹ̀ iná,Àìkàwé yanjú,Àìṣòwò yanjú,Iṣẹ́ ẹ̀gbin,B
2019,32,"""Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!"" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.
Láì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.",Kọ́lájọ ni ó,sin orílẹ̀-èdè,Ṣe òwò ọjà,ṣe ìranù,ríṣẹ́ tí ó dára,C
2019,32,"""Ẹ̀kọ́ dára! Ẹ̀kọ́ sunwọ̀n!"" Ariwo tí olùkọ́ àwọn Tèmiladé máa ń pa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìyí ní gbogbo ìgbà, àmọ́ orin ìmọ̀ràn yìí kò tà létí Tèmiladé. Ṣeun, Kọ́lájọ àti Kúnlé tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn Tèmiladé ni wọ́n jọ máa ń ṣe ìranù kiri. A tilẹ̀ máa fọ́nu pé kò dìgbà tí ènìyàn bá kàwé kó tó lówó lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, owó lòun ń fẹ́.
Láì fa ọ̀rọ̀ gùn, Jídé tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kàwé jáde ní Yunifásitì, ó sìnrú ìlú, ó ríṣẹ́ gidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rájé jẹun dáadáa. Owó rò yìí fẹjú mọ́ Tèmiladé ló bá pa ìwé kíkà tì pé òún fẹ́ sòwò. Ẹ̀gbọ́n àti àwọn òbí rẹ̀ dá a lókòwò, àmọ́ kò tó ọdún márùn-ún, iná sọ nílé ìtajà rẹ̀, ó sì run gbogbo ọjà náà. Báyìí ni Tèmiladé di ẹdun arilẹ̀. Ó gbìyànjú láti wáṣẹ́ pẹ̀lú ìwọ̀nba ìwé tó kà ṣùgbọ́n owó ìsẹ́pẹ́ àti iṣẹ́ ẹ̀gbin ni wọ́n fi ń lọ̀ọ́. Iwájú ò ṣe é lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣe é padà sí fún un: ojoojúmọ́ ló sì wá ń kábàámọ̀ pé òun kò kàwé yanjú.",Àkọlé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,ìranù ṣíṣe,Àìgba ìmọ̀ràn,Ìsìnrú ìlú,Ọjà títà,B
2019,33,"Òréré ayé, awo ojú
Ẹ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó
Ẹ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà
Ẹ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun
Àgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí
Ọmọ adáríhunrun sí sàkun ayé
Nítorí ojú làgbà á yá
Àgbà kan kì í yánu
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Oníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀
Ìdí abájọ táyé ò fi gún mọ́
Ẹ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́
Àkàṣù kò yó géńdé
Àkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún
Àṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́
Ayé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!",Èwo ni ó bá ayé mulẹ̀?,Onísọ̀nà,Ọmi òkun,Ẹmọ́,Òréré ayé,B
2019,33,"Òréré ayé, awo ojú
Ẹ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó
Ẹ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà
Ẹ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun
Àgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí
Ọmọ adáríhunrun sí sàkun ayé
Nítorí ojú làgbà á yá
Àgbà kan kì í yánu
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Oníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀
Ìdí abájọ táyé ò fi gún mọ́
Ẹ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́
Àkàṣù kò yó géńdé
Àkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún
Àṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́
Ayé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!",Ta ló ta àwọn aráyé jí nípa bí ayé ṣe rí?,Oníṣọ̀nà,Géńdé,Àgbà-ò-kọgbọ́n,Adélébọ̀,C
2019,33,"Òréré ayé, awo ojú
Ẹ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó
Ẹ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà
Ẹ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun
Àgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí
Ọmọ adáríhunrun sí sàkun ayé
Nítorí ojú làgbà á yá
Àgbà kan kì í yánu
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Oníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀
Ìdí abájọ táyé ò fi gún mọ́
Ẹ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́
Àkàṣù kò yó géńdé
Àkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún
Àṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́
Ayé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!",Àyọlọ̀ yìí sọ pé ayé àtijọ́,kún fún ìbéèrè,rọ ènìyàn lọ́rùn,pa ẹmọ́ run,ni oníṣọ̀nà lára,B
2019,33,"Òréré ayé, awo ojú
Ẹ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó
Ẹ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà
Ẹ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun
Àgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí
Ọmọ adáríhunrun sí sàkun ayé
Nítorí ojú làgbà á yá
Àgbà kan kì í yánu
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Oníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀
Ìdí abájọ táyé ò fi gún mọ́
Ẹ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́
Àkàṣù kò yó géńdé
Àkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún
Àṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́
Ayé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!","""Ṣẹ́ kọ́nà"" nínú àyọlò yìí túmọ̀ sí",yípo,gbàbọ̀dè,ṣèké,ṣàìsí,A
2019,33,"Òréré ayé, awo ojú
Ẹ wo òréré ayé bó ti tọ́ tó
Ẹ wò ó lọ sàà débi tí ó ti ṣẹ́ kọ́nà
Ẹ wò ó bó ti ṣe lẹlẹ bí omi òkun
Àgbà-ò-kọgbọ́n ló pe àkíyèsí
Ọmọ adáríhunrun sí sàkun ayé
Nítorí ojú làgbà á yá
Àgbà kan kì í yánu
Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí
Oníṣọ̀nà kú igbá ò ṣe é sọ
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀
Ẹ jẹ́ á bira wa léèrè ọ̀rọ̀
Ìdí abájọ táyé ò fi gún mọ́
Ẹ̀kọ kọ́bọ̀-kan-àbọ̀ kò yó ọmọ ọwọ́ mọ́
Àkàṣù kò yó géńdé
Àkàrà sísì kò tó adélébọ̀ í mùkọ ọ̀ọ́dúnrún
Àṣé ayé ti ṣẹ́ kọ́nà mọ́ wa lọ́wọ́
Ayé ò tọ́ mọ́ bí i tàtẹ̀yìn!",Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Ọmọ adáríhunrun,Ìwoṣàkun ayé,Ìdí abájọ,Ọ̀wọ́n oúnjẹ,B
2020,34,"""Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.
Àbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.
Tádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà
fi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.",Tolú jẹ́ [MASK],ẹ̀gbọ́n Tádé,àbúrò Táyọ̀,ọkọ Títí,Dáúdù Akinadé,B
2020,34,"""Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.
Àbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.
Tádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà
fi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.",Ibo ni wọ́n ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́?,Òró,Àbújá,Òkeehò,Ọ̀fà,D
2020,34,"""Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.
Àbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.
Tádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà
fi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.",Gbádébọ̀ jẹ́ ọmọ,àbúrò bàbá Títílayọ̀,àbúrò l̀yá Títílayọ̀,bàbá Tádé,ìyá Tọ́ba,A
2020,34,"""Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.
Àbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.
Tádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà
fi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.",Oṣù tí Títilayọ̀ wọ ilé ọkọ ni ó,bímọ,lóyún,lọ sìnrú ìlú,lọ mọ Òkeehò,A
2020,34,"""Akọ ni ògìdán ń bí' lọ̀rọ̀ Akinadé àti Tọ́lání, aya rẹ̀. Tádé Dáúdù, Tọ́ba, Táyọ̀ àti Tolú sì tẹ̀lé e ní ṣíṣẹ̀-ǹ-tẹ̀lé. Títíláyọ̀ tí ó di ìyàwó Tádé nìkan ni àwọn òbí tirẹ̀ bí. Kí ó má jẹ òun nìkan nínú ilé, ló mú kí àwọn òbi rẹ̀ gba Gbádébọ̀ àti Kíkẹ́lọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ sọ́dọ̀.
Àbújá ni Tádé àti Títílayọ̀ ti pàdé nih àsìkò tí wọ́n lọ sin ilẹ̀ bàbá wọn. Bí eré, bí àwàdà, ọ̀rọ ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín wọn. Lẹ́yìn oṣù keje tí wọ́n pàdé, wọ́n pinnu láti fẹ́ ara wọn.
Tádé mú, Títílayọ̀ lọ sí ìlú rẹ̀, Òkeehò, láti lọ ṣàfihàn Títílayọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Inú Tádé dùn pé àwọn òbí òun kò rí àbùkù lára àfẹ́sọ́nà òun. Tọwọ́-tẹsẹ̀ ni àwọn òbí Títílayọ̀ náà
fi gba Tádé gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ wọn. Ọmọ Ọ̀fà, tí ó tún tan mọ́ Òró ni Títílayọ̀, Ọ̀fà ni wọ́n sì ti ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Oṣù kẹta lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó alárinrin. Gbogbo àwọn àbúrò Tádé ni ó péjọ síbẹ̀. Títílayọ̀ kò mú oṣù náà jẹ. Oṣù kẹsàn-án gééré lẹ́yìn ìgbéyàwó ni Títíayọ̀ bí ọmọkùnrin kan.",Àkọ́lé tí ó bá àoykà yìí mu jùlọ ni,Ìgbéyàwó kan,Ìsìnrú ìlú,Ìdílé Akinadé,Gbígba ọmọ tọ́,A
2020,35,"Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù
Ọgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò
Kò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù
Bá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́
Bí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn
Bí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre
Bí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ
Bí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà
Wò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ
Mo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn
Ìfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀
Aláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru
Àwọn tí kìí fojú róhun olóhun
Alágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó
Ẹni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé
Ẹyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò
Èyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin
Ọ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!",Kí ni akéwì fi ìlà méjì àkọ́kọ́ ewì yìí ṣe?,Èébú,Ìmọ̀ràn,l̀báwí,Ẹ̀gọ́,B
2020,35,"Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù
Ọgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò
Kò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù
Bá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́
Bí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn
Bí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre
Bí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ
Bí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà
Wò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ
Mo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn
Ìfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀
Aláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru
Àwọn tí kìí fojú róhun olóhun
Alágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó
Ẹni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé
Ẹyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò
Èyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin
Ọ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!",Akéwi sọ pé àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run kàn máa ń,fohun burúkú kọ́mọ,gbébi fáláre,gbowó ẹ̀yìn,ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà,D
2020,35,"Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù
Ọgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò
Kò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù
Bá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́
Bí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn
Bí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre
Bí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ
Bí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà
Wò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ
Mo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn
Ìfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀
Aláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru
Àwọn tí kìí fojú róhun olóhun
Alágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó
Ẹni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé
Ẹyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò
Èyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin
Ọ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!",Ta ni akéwì sọ pé ó máa gbowó ẹ̀yìn?,Olùkọ́,Kólékóle,Ọlọ́pàá,Adájọ́,C
2020,35,"Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù
Ọgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò
Kò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù
Bá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́
Bí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn
Bí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre
Bí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ
Bí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà
Wò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ
Mo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn
Ìfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀
Aláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru
Àwọn tí kìí fojú róhun olóhun
Alágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó
Ẹni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé
Ẹyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò
Èyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin
Ọ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!",[MASK] ni akéwì sọ pé kìí kó owó pé fún ọlọ́jà.,Alágbàtà,Arìndeòru,Onífàyàwọ́,Apààyàn,A
2020,35,"Bó o bá réèyan tó fówó láfẹ̀ẹ́jù
Ọgbọ́n inú ni kó o fi máa bá a lò
Kò síwà búburú kan tí irú wọn kò lè wù
Bá a fiwọ́n sípò iyì, wọn kò jẹ́ ṣòótọ́
Bí wọ́n jọ́lọ́paá, wọn a gbowó ẹ̀yìn
Bí wọ́n jádájọ́, wọn á gbẹ́bi fáláre
Bí wọ́n jólùkọ́, wọn á fohun burúkú kọ́mọ
Bí wọ́n jójìíṣẹ́ Ọlọ́run, wọn á ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà
Wò wọ́n léèkan kó o kọjú sí ibi ò ń lọ
Mo bẹ̀ ọ́, má tilẹ̀ fara wé wọn
Ìfẹ́-owó ṣáà ni gbòǹgbò ẹ̀ṣẹ̀
Aláṣọ dúdú tó ń rìn kiri lóru
Àwọn tí kìí fojú róhun olóhun
Alágbàtà tó pa ṣíṣi tó pè é ní tọ́rọ́ fólówó
Ẹni tó ń bàṣírí apààyàn àti kólékólé
Ẹyí tí ó ń ṣe fàyàwọ́, èyí tí ń tọwọ́ bàpò alápò
Èyí tó ń parọ́ fún ni bí ẹni láyin
Ọ̀nà àtijí ohun olóhun mọ́ tiwọn ni wọ́n ń ṣe kiri!",Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Fífi ara wé ẹlòmìíràn,Níní ìfẹ́ owó jù,Gbígbé ẹ̀bi fún aláre,Kíki ọwọ́ bọ àpò alápò,B
2021,36,"Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.
Tanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.",Ẹni tí ó ṣokùnfà ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún Tanímọ̀la ni,Adérọ̀gbà,Moẹ́erere,Ayọ̀kúnnú,Adédọjà,B
2021,36,"Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.
Tanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.",Adédọjà jẹ́,oníṣòwò ńlá,ọ̀gá-àgbà ilé-ẹ̀kọ́,gbajúmọ̀ agbẹjọ́rò,aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́,A
2021,36,"Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.
Tanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.",Tanímọ̀la ni ó di,atọrọjẹ nígbẹ̀yìn,aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́,agbẹjọ́rò pàtàkì,ọ̀gá-àgbà ilé-ẹ̀kọ́,C
2021,36,"Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.
Tanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.",Ta ni agbójúlógún?,Mofẹ́rere,Adérọ̀gbà,Adédọjà,Ayọ̀kúnnú,D
2021,36,"Oma pọ̀-bi-ọsàn-bọ́ ni Ayọ̀kúnnú. Àkẹ́bàjẹ́ ọmọ ọlọ́rọ̀ ni. Inú owó ni àwọn òbí rẹ̀ bíi sí. Oníṣòwò ńlá ni Adédọjà, bàbá rẹ̀. Owó àwọn òbí rẹ̀ yìí ni kò jẹ́ kí ó fojú sẹ́kọ́ọ rẹ̀ tí ó fi rò pé bí òun kò tilẹ̀ kàwé, owó àwọn òbí òun tó òún ná títí dọjọ́ alẹ́.
Tanímọ̀la ní tirè, oúnjẹ ọ̀sán kì í bá ti àárọ̀ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti pinnu pé ibi tí àwọn òbí òun kò lè dé ní rere, òun yóò sa ipá òun láti débẹ̀. Gbogbo akitiyan àwọn òbí Ayọ̀kúnnú láti ri pé ó kàwé ni ó já sí pàbó. Mofẹ́rere, ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ wọn fi orúkọ Tanímọ̀la ráńṣẹ́ sí Adérọ̀gbà, aláṣẹ ètò-ẹ̀kọ́ fún ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, Tanímọ̀la sì lo ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí dé Yunifásítì.
Nígbẹ̀yìn, wọ́n lé Ayọ̀kúnnú kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí àìmọ̀wé rẹ̀. Lẹ́yin ikú àwọn òbí rẹ̀ tí àwọn báǹkì wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun ìní wọn ni ó tó mọ̀ pé owó báǹkì ni àwọn òbí òún ń ná. Kò rówó ná mọ́ torí pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Èyí ni ó fà á tí ó fi di atọrọjọ kẹ́yìn ayé rẹ̀. Tanímọ̀la ní tirẹ̀ gboyè agbẹjọ́rò, ó si di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká nítorí àṣeyege tí ó máa ń ṣe níwájú adájọ́.",Ìpinnu Ayọ̀kúnnú ni pé kí òun,di oníṣòwò ńlá,di adájọ́,múra sí ẹ̀kọ́ òun,máa ná owó òbí òun,D
2021,37,"Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.
Lóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!
Irun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.",[MASK] kì í ṣe àmúyọ ọmọ Yorùbá,Mímọ èdé lò,Ṣíṣe ara lọ́ṣọ̀ọ́,Pípèsè oúnjẹ ìbílẹ̀,Jíjó irun níná,D
2021,37,"Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.
Lóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!
Irun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.","Nípasẹ àṣà wo ni a fi so Yorùbá di ""ọmọ káàárọ̀-ò-jíire""?",Ìmúra,Ìkíni,ìpèsè oúnjẹ́,Irun dídì,B
2021,37,"Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.
Lóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!
Irun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.",Èwo ni ó tàbùkù àṣà ìwọṣọ Yorùbá?,Sísọ ède Gẹ̀ẹ́sì,Lílo wíìgi,Irun dídì okùnrin,Rírìn ìhòòhò,D
2021,37,"Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.
Lóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!
Irun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.",Oríṣi irun dídì wo ni a mẹ́nu bà gbẹ̀yìn nínú àyọkà yìí,Korobá,Pàtẹ́wọ́,Kọjúsọ́kọ,Ṣùkú,A
2021,37,"Àṣa Yorùbá rẹwà púpọ̀; ó sì jẹ́ ohun ìwúrí fún gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-ò-jíire láti máa gbé e lárugẹ. Lára àwọn àmúye àṣa Yorùbá ni mímọ Èdè é lò, kí ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀, kí ó sì fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ yọ. Ìpèsè oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá, ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ àti wíwọ aṣọ tó bá òde mu; gbogbo àwọn ìwọ̀nyí ni Yorùbá fi ń yangàn láwùjọ.
Lóde òní, àṣa àjèjì ti gba gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí lọ́wọ́ọ púpọ̀ nínú wa. Ède Gẹ̀ẹ́sì ni púpọ̀ ọmọ Yorùbá ń fọ̀. Gbogbo aṣọ tó buyì kẹ́wà tí ó dáàbò bo gbogbo ògo tí Ọlọ́run fún wa ti ń di ohun ìgbàgbé lọ. Ìhòòhò ni àwọn ọmọ mìíràn ń rìn kiri ìlú!
Irun dídì bíi pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, ṣùkú, korobá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó máa ń móge rẹwà ti fẹ́rẹ̀ di àfìsẹ́hìn téégún aláré ń fiṣọ. Àṣà irun jíjó, gbígbé irun àgùntàn lérí ti gbalẹ̀ kan láàárín ọ̀pọ̀ obìnrin, tí ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin sì ń dirí bíi elégún Ṣángó.",Àkọlé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Àṣà Yorùbá ń kú lọ,Aṣọ wíwọ̀ lóde òní,Irun dídì nílẹ̀ Yorùbá,júṣe ọmọ Yorùbá àtàtà,A
2022,38,"Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.
Ilé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí
Afúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.
Owó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.",ìlú wo ni àwọn adigunjalè ti ṣiṣẹ́ láabi?,Kórípé,Tèmípémi,Ìfẹ́lódùn,Ṣọ́balójú,C
2022,38,"Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.
Ilé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí
Afúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.
Owó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.",Mélòó ni àwọn adigunjalè náà lápapọ̀?,Ogójì,Mẹ́rìnlá,Mẹ́fà,Mẹ́rìnlélógún,C
2022,38,"Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.
Ilé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí
Afúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.
Owó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.",Ilé ìfowópamọ́ wo ni àwọn ọlọ́ṣà náà bẹ́wọ̀ ṣìkejì?,Afúyẹ́gẹgẹ,Ọmọlèrè,Owólòwò,Tẹ́wọ́gbare,A
2022,38,"Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.
Ilé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí
Afúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.
Owó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.",Ilé ìfowópamọ́ wo ni wọ́n ti pa ènìyàn mẹ́rìnlá?,Ọmọlèrè,Tẹ́wọ́gbare,Afúyẹ́gẹgẹ,Owólòwò,B
2022,38,"Ọjọ́ mánigbàgbé lọ́jọ́ tí àwọn adigunjalẹ̀ kógun wá sí ìlú l̀fẹ́lódùn láti ṣọṣẹ́ láwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú ọ̀hún. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lé mẹ́fà ni wọ́n gbé wá láti pitú ọwọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé ọlọ́ṣà mẹ́rin.
Ilé ìfowópamọ́ Ọmọlèrè tí ó wà ní àdúgbò Ayénirọ́mọ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sí kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú sí
Afúyẹ́gẹgẹ ní àdúgbò Tèmípémi. llé ìfowópamọ́ kẹta tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn ni Owólòwò tí ó wà ní àdúgbò Ṣọ́balójú. Báǹkì Tẹ́wọ́gbare ni ilé ìfowópamọ́ kẹẹ̀rin tí wọ́n bẹ̀wò. Wọ́n fi ẹ̀mí mẹ́rìnlá ṣòfò ní ilé ìfowópamọ́ ọ̀hún. Ṣe ni ipọ́n ń tọ tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe bàlà ní àdúgbò Moríre tí báǹkì náà wà. Ogójì ẹ̀mí ni wọ́n sì dá légbodò lápapọ̀ lọ́jọ́ burúkú yìí.
Owó tí wọ́n rí gbé lọ kò tó ohun tí ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò sí. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ wọ́n ní ojú ọ̀nà ìlú Kórípé sí Afẹ́rẹ̀.",Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Ìfẹ́ Owó,Aàbò ní ilẹ̀ wa,Àwọn agbófinró,Eèmọ́ Wọ̀lú,B
2022,39,"Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún
sí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.
Inú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere
láìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.",Ta ni ó jẹ ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́?,Kọ́ládé,Pẹ̀lúmi,Ọmọ́wùmí,Bísọ́lá,C
2022,39,"Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún
sí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.
Inú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere
láìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.",[MASK] ni ó ṣe agbátẹrù ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́.,Ọ̀rẹ́wùmí,Kọ́ládé,Pẹ̀lúmi,Mákànánjúọlá,A
2022,39,"Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún
sí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.
Inú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere
láìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.",Mílíọ̀nù náírà mélòó ni ẹni tí ó ẹe ipò kìíní gbà?,Ọ̀kan,Méjì,Mẹ́tà,Mẹ́rin,B
2022,39,"Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún
sí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.
Inú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere
láìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.",Ọmọ́wùmi jẹ́ ọmọ [MASK],Bísọ́lá,Ọ̀rẹ́wùmí,Bánkẹ́,Adéjọkẹ́,D
2022,39,"Ọmọ́wùmí ṣe ìdánwò láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Erínfọlámí, Olóyè Táyé Ọ̀rẹ́wùmí ṣe agbátẹrù rẹ̀. Àwọn mẹ́fà, Bísọ́lá, Kọ́ládé, Adéjọkẹ́, Pẹ̀lúmi, Ọmọ́wùmi àti Tómilẹ́rìn-ín ni wọ́n jọ díje fún ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Ọmọ́wùmí, ọmọ atàpátadìde kan ni ó jáwé olúborí. Orí Gómìnà wú lọ́pọ̀lọpọ̀, ó fún Ọmọ́wùmí ní ẹ̀bùn owó mílíọ̀nù méjì náírà ní àfikún
sí ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ tó fún un.
Inú Mákànánjúọlá, bàbá Ọmọ́wùmí dùn gidi gan-an fún ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ tí ó yí padà sí rere
láìròtì. Ṣèbí tálákà paraku ni òun àti Bánkẹ́, ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ títí di àsìkò tí ọmọ wọ́n jẹ ẹ̀bùn owó tabua àti ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ yìí. Wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ọ Ọlọ́run tí ó kọjú sí wọn ṣe lóore.",Àkọ́lé tí ó bá àyọkà yìí mu jùlọ ni,Ẹ̀bùn owó,Ẹni a fẹ́ la mọ̀,Ẹní máa joyin inú àpáta,Bá ò kú ìṣe ò tán,D