translation
dict |
---|
{
"en": "If party members and government officials are not aware of this, it means that they are not politically sensitive and have lost their progressiveness.",
"yo": "Bí ẹlẹ́gbẹ́ olóṣèlú kò bá mọ èyí, a jẹ́ wípé wọn kò ní ìkọbiarasí ìṣèlú wọ́n sì ti pàdánù ìlọsíwájúu wọn."
} |
{
"en": "The commentary references the history of the Eight-Nation Alliance, a coalition formed in response to the Boxer Rebellion in China between 1899 and 1901 when Chinese peasants rose up against foreign, colonial, Christian rule and culture.",
"yo": "Awuyewuye náà tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá Eight-Nation Alliance, ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan tí a dá ní ìdáhùnsí Tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun Akànṣẹ́ ní China láàárín-in ọdún 1899 àti 1901 nígbàtí àwọn àgbẹ̀ rokoroko fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba amúnisìn, ètò ìṣèlú ní ìlànà Krìstẹ́nì àti àṣà."
} |
{
"en": "It further argues that the birthday of Mao Zedong, the founding father of the People's Republic of China, should be treated as China’s Christmas:",
"yo": "Síwájú sí i, ó ní wípé ọjọ́ ìbíi Mao Zedong, bàbá ìsàlẹ̀ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti Èèyàn-an China, ni ó yẹ kí a kà sí Kérésìmesì ìlú China:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "The first Chairman of the Republic of China Mao Zedong had saved people from misery.",
"yo": "Alága àkọ́kọ́ Ìlú-tí-kò-fi-ọba-jẹ ti China Mao Zedong ti yọ àwọn ènìyàn nínú ìṣòro."
} |
{
"en": "We should make his birthday Chinese Christmas.",
"yo": "A gbọdọ̀ sọ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ di Kérésìmesì China."
} |
{
"en": "Act and reject Western festivals.",
"yo": "Gbé ìgbésẹ̀ kí o kọ àjọ̀dún Òyìnbó."
} |
{
"en": "But many on Weibo found these arguments illogical.",
"yo": "Àmọ́ àwọn ènìyàn kan lórí Weibo kò rí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n kankan nínú àríyànjiyàn wọ̀nyí."
} |
{
"en": "One commentator said:",
"yo": "Ẹnìkan sọ pé:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "When Westerners celebrate the Chinese Lunar New Year, Chinese people are so proud and see the phenomena as the revival of Chinese traditional culture...",
"yo": "Bí àwọn Òyìnbó bá ń ṣe àjọyọ̀ Ọdún Òṣùpá Tuntun, àwọn aráa China á gbéraga wọ́n á sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìdàgbà ìsọjí àṣà ìbílẹ̀ China..."
} |
{
"en": "When Chinese people celebrate Western festivals, what's the point of labeling them as culture invasion?",
"yo": "Bí àwọn aráa China bá ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó, kí ni ìdí tí a fi kà wọ́n sí ìgbógunti àṣà?"
} |
{
"en": "Young people celebrate Western festivals for fun and joy.",
"yo": "Àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó nítorí àríyá àti fún ayọ̀."
} |
{
"en": "The festivals can boost consumption, what’s wrong with that?",
"yo": "Àwọn àjọ̀dún wọ̀nyí lè mú ìkóúnjẹjẹ gbòòrò, kí ni ó burú nínú ìyẹn?"
} |
{
"en": "Some people try to draw connection between celebrating Christmas and the national humiliation that happened 160 years ago.",
"yo": "Àwọn kan gbèrò wọ́n fẹ́ gbé àjọyọ̀ Kérésìmesì fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìrẹ̀sílẹ̀ ìlú tí ó wáyé ní ọgọ́jọ ọdún sẹ́yìn."
} |
{
"en": "For what?",
"yo": "Fún kí ni?"
} |
{
"en": "Social pressure, self-censorship",
"yo": "Ẹgbẹ́kíkó, ìkóraẹni-níjàánu"
} |
{
"en": "The flood of anti-Christmas comments on social media has generated pressure for some social media users to self-censor.",
"yo": "Àgbàrá òdì ọ̀rọ̀ sí Kérésìmesì ti ṣàn gba orí ẹ̀rọ-alátagbà ó sì ti mú kí àwọn òǹlò kan ó kó ara wọn ní ìjánu."
} |
{
"en": "A Weibo user expressed frustration:",
"yo": "Ònlo Weibo kan fi ẹ̀hónú hàn:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "Christmas is approaching.",
"yo": "Kérésìmesì ń bọ̀ lọ́nà dẹ̀dẹ̀."
} |
{
"en": "In my friend circle, anti-Western festival camps and anti-anti Western festival camps are debating.",
"yo": "Ní agbo ọ̀rẹ́ẹ wa, àgọ́ alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó àti alòdìsí alòdìsí àjọ̀dún Òyìnbó ń ṣe àríyànjiyàn."
} |
{
"en": "Whether one likes to celebrate or not is none of others’ business, why do people just have to force others to agree with their view?",
"yo": "Kò kan ẹnikéni bóyá èèyàn féràn àjọyọ̀ tàbí kò fẹ́, kí ni ó dé tí àwọn ènìyàn ṣe fẹ́ràn láti máa fi túláàsì mú ẹlòmíràn gba èròńgbà ti wọn?"
} |
{
"en": "Everyone standing on one side is too crowded.",
"yo": "Ojú kan tí gbogbo ènìyàn dúró sí ti kún."
} |
{
"en": "For those of us who are in the middle, in order to create a balance, we have to stand on the other side.",
"yo": "Fún àwa tí a wà láàárín, kí a ba mú un dọ́gba, a ní láti dúró sí ẹ̀gbẹ́ kejì."
} |
{
"en": "School notice against the celebration of Western festivals on campus.",
"yo": "Ìkìlọ̀ lórí ìtako àjọ̀dún Òyìnbó ní inú ọgbà ilé-ìwé."
} |
{
"en": "Pressure goes beyond social media platforms, extending to institutions such as schools and corporations.",
"yo": "Awuyewuye ti kọjáa ti gbàgede orí ẹ̀rọ-alátagbà, ó kàn dé ilé-ìwé àti àjọ ìlú."
} |
{
"en": "Some Weibo users have shared school notices that were distributed to students.",
"yo": "Àwọn òǹlo Weibo kan ti pín ìkìlọ̀ ilé-ìwé ti a fún akẹ́kọ̀ọ́."
} |
{
"en": "One of the notices (right) refers to the \"Suggestions\" mandate and urges teachers and students to resist Western style celebrations.",
"yo": "Ọ̀kan nínú ìkìlọ̀ náà (ọ̀tún) ń tọ́ka sí òfin \"Ìmọ̀ràn\" ó sì rọ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ àyájọ́ tí ó fi ara jọ ti Òyìnbó sílẹ̀."
} |
{
"en": "It also demands students to spread anti-Western messages to friends and family members on Wechat and other mobile messaging applications.",
"yo": "Bákan náà ni ìkìlọ̀ rọ akẹ́kọ̀ọ́ láti fọ́n iṣẹ́-ìjẹ́ òdì-ọ̀rọ̀ ìgbógunti àṣà Òyìnbó ká sí ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ lórí WeChat àti lórí àwọn irinṣẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀rọ-alátagbà mìíràn."
} |
{
"en": "One mother was surprised to find her child rejecting her offer of a Christmas gift. She wrote on Weibo:",
"yo": "Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún ìyá kan nígbàtí ọmọọ rẹ̀ kọ ẹ̀bùn Kérésìmesì. Ìyá kọ sórí Weibo:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "Mother: Baby, what do you want for Christmas gift?",
"yo": "Ìyá: Ọmọ mi, ẹ̀bùn wo lo fẹ́ fún Kérésìmesì?"
} |
{
"en": "Child: I will not celebrate Western festivals Christmas is not a Chinese people’s festival.",
"yo": "Ọmọ: Èmi ò ní ṣe àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó kì í ṣe àjọ̀dún ìlúu China."
} |
{
"en": "OK, you are definitely an obedient baby of the Party and the People.",
"yo": "Ó dáa, dájúdájú onígbọràn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn ará ìlú ni ọ́."
} |
{
"en": "However, high school and college students were more critical.",
"yo": "Síbẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ṣe àròjinlẹ̀."
} |
{
"en": "One student questioned school policy on Weibo:",
"yo": "Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ìbéèrè lórí òfin ilé-ìwé lórí Weibo:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "The school has banned Christmas decorations on campus and forbidden students to exchange gifts so as to campaign against Western festivals.",
"yo": "Ilé-ìwé ti gbé ẹsẹ̀ lé ìṣẹ̀ṣọ́ọ Kérésìmesì nínú ọgbà ó sì ti sọ pàṣìpàrọ̀ ẹ̀bùn di èèwọ̀ ní ìpolongo ìtako àjọ̀dún Òyìnbó."
} |
{
"en": "Are all these measures to enhance and promote Chinese culture or a sign of losing confidence on one’s own culture?",
"yo": "Ǹjẹ́ fún ìdàgbàsókè àṣà ilẹ̀ China ni gbogbo ọ̀nà yìí tàbí àmì ìpàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ ẹni?"
} |
{
"en": "Some have chosen to celebrate the festival in secret. A Weibo user said:",
"yo": "Àwọn kan ti yan ìṣàjọyọ̀ àjọ̀dún náà ní ìkọ̀kọ̀. Òǹlo Weibo kan sọ:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "The company has forbidden the celebration of Western festivals. But the secretary in the personnel department has handed out a Christmas apple [common Christmas gift] to the staff members in secret.",
"yo": "Ilé-iṣẹ́ ti sọ ayẹyẹ àjọyọ̀ àjọ̀dún Òyìnbó di èèwọ̀. Ṣùgbọ́n akọ̀wé láti ẹ̀ka ètò-òṣìṣẹ́ ti fi òró Kérésìmesì (ẹ̀bùn Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀) fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀."
} |
{
"en": "Let’s wish for peace.",
"yo": "Ẹ jẹ́ kí a fẹ́ àlàáfíà."
} |
{
"en": "Another Weibo user expressed his view with a Christmas wish:",
"yo": "Òǹlo Weibo mìíràn fi èròǹgbàa rẹ̀ hàn pẹ̀lú ohun tí ó fẹ́ fún Kérésìmesì:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "Merry Christmas!",
"yo": "Ẹ kú ọdún Kérésìmesì!"
} |
{
"en": "I love you god!",
"yo": "Mo nífẹ̀ẹ́-ẹ̀ rẹ olúwa!"
} |
{
"en": "Santa Claus, pls give me a big big sock with freedom in it.",
"yo": "Bàba Kérésìmesì, jọ̀wọ́ fún mi ní ìbọsẹ̀ nílá gbàǹgbà pẹ̀lú òmìnira nínúu rẹ̀."
} |
{
"en": "An all-female flight crew makes history in Mozambique",
"yo": "Òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú olóbìnrin nìkan wọ ìwé ìtàn ní Mozambique"
} |
{
"en": "Mozambique's first all-female crew | Photo used with permission from Meck Antonio.",
"yo": "Ikọ̀ awakọ̀ òfuurufú olóbìnrin àkọ́kọ́ irúu rẹ̀ ní Mozambique | A lo àwòrán pẹ̀lú àṣẹ láti ọwọ́ Meck Antonio."
} |
{
"en": "It is a historic day: that is how many Mozambicans regard December 14, 2018 when, for the first time in the country's civil aviation history, an airplane was operated solely by women.",
"yo": "Ọjọ́ ìtàn ni ọjọ́ yìí: ojú yìí ni ogunlọ́gọ̀ ọmọ-ìlú Mozambique fi wo ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ 14, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2018 nígbà tí, fún ìgbà àkókọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé ètò ọkọ̀ òfuurufú ìlú náà, tí obìnrin jẹ́ atukọ̀."
} |
{
"en": "The crew for flight TM112/3, which traveled between the capital, Maputo, and Manica — an air distance of 442 miles — was captain Admira António, co-pilot Elsa Balate, cabin chief Maria da Luz Aurélio, and flight attendant Débora Madeleine.",
"yo": "Ikọ̀ bàlúù TM112/3, tí ó rin ìrìn àjò láti olú ìlú, Maputo, àti Manica — tí jíjìn sí ara wọn tó máìlì 442 — ni a tí rí atukọ̀ Admira António, atukọ̀ kejì Elsa Balate, olóyè ọkọ̀ Maria da Luz Aurélio, àti òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ Débora Madeleine."
} |
{
"en": "The women are members of MEX, an entity originally created as the Special Operations Department of LAM — Linhas Aéreas de Moçambique.",
"yo": "Àwọn obìnrin wọ̀nyí wà nínú ẹgbẹ́ MEX, ilé-iṣẹ́ tí a dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àkànṣe LAM — Linhas Aéreas de Moçambique."
} |
{
"en": "In 1995, it began operations as an independent airline, Mozambique Express.",
"yo": "Ní 1995, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú aládàáni , Mozambique Express."
} |
{
"en": "A congratulatory Facebook status update posted by feminist activist Eliana Nzualo, has so far attracted nearly 450 comments, been shared more than 460 times, and garnered close to 2,000 reactions:",
"yo": "Àtẹ̀jáde ìkíni orí Facebook láti ọwọ́ ajàfúnẹ̀tọ́ obìnrin Eliana Nzualo, ti ní ìsọsí tí ó tó 450, tí a ti pín tó ìgbà 460, àti pé ọ̀pọ̀ èsì tí ó tó 2,000 ni ó gbà:"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "A HISTORIC DAY – All-female crew",
"yo": "ỌJỌ́ ÌTÀN – Ikọ̀ ọkọ̀ òfuurufú"
} |
{
"en": "Congratulations MEX!",
"yo": "MEX kú oríire!"
} |
{
"en": "Congratulations crew!",
"yo": "Ikọ̀ ẹ kú oríire!"
} |
{
"en": "Congratulations, Mozambique!",
"yo": "Mozambique, kú oríire!"
} |
{
"en": "For more women in all sectors.",
"yo": "Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin nínú iṣẹ́ gbogbo."
} |
{
"en": "Social activist Mauro Brito added that women should be proud \"when [they] are represented in various sectors\":",
"yo": "Àjàfúnẹ̀tọ́ ìkẹ́gbẹ́ Mauro Brito sọ ní tirẹ̀ wípé obìrin gbọ́dọ̀ ní ìgbéraga \"nígbàtí [wọ́n] bá jẹ́ aṣojú nínú iṣẹ́ gbogbo\":"
} |
{
"en": "Translation Original Quote",
"yo": "Ìtúmọ̀ Ìtúnwí-ọ̀rọ̀ Ọlọ́rọ̀ gan-an"
} |
{
"en": "In aviation there are few women, very few, this is not only here but in the whole world.",
"yo": "Obìnrin kò pọ̀ nínú iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe rí káríayé."
} |
{
"en": "I imagine the women who thought this profession was for men only, should feel proud.",
"yo": "Mo rò ó wípé àwọn obìnrin tí ó ronú láti ṣe iṣẹ́ tí ọkùnrin máa ń ṣe, gbọdọ̀ gbéraga."
} |
{
"en": "Mozambique is not alone.",
"yo": "Mozambique nìkan kọ́."
} |
{
"en": "In August 2018, in a first for South Africa's national carrier SAA, an intercontinental flight with an all-female crew took to the skies to transport passengers from Johannesburg to Sao Paulo, Brazil.",
"yo": "Ní oṣù Ògún ọdún 2018, nínú ọkọ̀ òfuurufú ìlú apá Gúúsù Ilẹ̀-Adúláwọ̀ SAA, ìrìnàjò ìlú dé ìlú pẹ̀lú ikọ̀ olóbìnrin fò ní ojú sánmà wọ́n sì kó èrò láti Johannesburg sí Sao Paulo, Brazil."
} |
{
"en": "Eight months earlier, in December 2017, Ethiopian Airlines operated its first ever flight staffed by an all-female crew.",
"yo": "Oṣù méjìlá sẹ́yìn, ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2017, Ilé-iṣẹ́ Ọkọ̀ òfuurufú Ethiopia fún ìgbà àkókọ́ gbé ikọ̀ òṣìṣẹ́bìnrin fò."
} |
{
"en": "From pilots to cabin crew, check-in staff to flight dispatchers, the flight — from Addis Ababa in Ethiopia to Lagos in Nigeria — was (wo)manned entirely by women.",
"yo": "Awọn atukọ̀ títí kan òṣìṣẹ́ gbogbo, ọkọ̀ òfuurufú láti Addis Ababa ní Ethiopia sí Èkó ní Nàìjíríà — jẹ́ obìnrin pátápátá porongodo."
} |
{
"en": "Why are African governments criminalising online speech? Because they fear its power.",
"yo": "Kí ló dé tí ìjọba Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ń f'òfin de ọ̀rọ̀ sísọ orí-ayélujára? Nítorí wọ́n bẹ̀rù agbára rẹ̀."
} |
{
"en": "Students at Haromaya University in Ethiopia displaying a quasi-official anti-government gesture.",
"yo": "Akẹ́kọ̀ọ́ Ifásitì Haromaya ní Ethiopia ń fi àmì ìtako ìjọba hàn."
} |
{
"en": "Photo shared widely on social media.",
"yo": "Àwòrán tí a pín lórí ẹ̀rọ-alátagbà."
} |
{
"en": "Africa’s landscape of online free speech and dissent is gradually, but consistently, being tightened.",
"yo": "Ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára ti ń rí ìfúnpa láti ọwọ́ ìjọba díẹ̀ díẹ̀."
} |
{
"en": "In legal and economic terms, the cost of speaking out is rapidly rising across the continent.",
"yo": "Nínú ìlànà òfin àti ọ̀rọ̀ Ajé, iye òmìnira ọ̀rọ̀ ń dìde kárí Ilẹ̀-Adúláwọ̀."
} |
{
"en": "While most governments are considered democratic in that they hold elections with multi-party candidates and profess participatory ideals, in practice, many operate much closer dictatorships — and they appear to be asserting more control over digital space with each passing day.",
"yo": "Nígbà tí àwọn ìjọba kan mọ rírì ètò ìjọba àwa-arawa nípasẹ̀ ṣíṣe ìbò pẹ̀lú ọlọ́pọ̀-ẹgbẹ́ òṣèlú àti sọ nígbangba nípa àjọṣe, nínú ìṣe, ọ̀pọ̀ máa ń lo àṣẹ tí ò ṣe é yí padà — wọ́n sì ń lo agbára àṣẹ yìí lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá bí ọjọ́ ṣe ń gun orí ọjọ́."
} |
{
"en": "Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, and Benin have in the recent past witnessed internet shutdowns, the imposition of taxes on blogging and social media use, and the arrest of journalists.",
"yo": "Cameroon, Tanzania, Uganda, Ethiopia, Nigeria, àti Benin ti ní Ìtìpa Ẹ̀rọ-ayélujára, ìjọba ti fi owó-orí lé lílo búlọ́ọ̀gù àti ẹ̀rọ-alátagbà, wọ́n sì ti fi ọwọ́ ṣìgún òfin mú oníròyìn."
} |
{
"en": "Media workers and citizens have been jailed on charges ranging from publishing “false information” to exposing state secrets to terrorism.",
"yo": "Òṣìṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ọmọ-ìlú ti di èrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn àtẹ̀jáde “ìròyìn irọ́” títí kan ìkóròyìn ìkòkọ̀ ìlú sí etí ìgbọ́ ẹgbẹ́ afẹ̀míṣòfò."
} |
{
"en": "At the recent Forum of Internet Freedom in Africa (FIFA) held in Accra, Ghana, a group of panelists from various African countries all said they feared African governments were interested in controlling digital space to keep citizens in check.",
"yo": "Ní ibi Àpérò Òmìnira Ẹ̀rọ-ayélujára ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (FIFA) tí ó wáyé ní Accra, Ghana, ikọ̀ akópa láti àwọn ìlú ilẹ̀ Adúláwọ̀ pátá sọ wípé kò ní ṣe ẹnu rere bí ìjọba bá fi òfin de ọmọ-ìlú tí ó ń lo ẹ̀rọ-ayárabíaṣá."
} |
{
"en": "Many countries have statutes and laws which guarantee the right to free expression.",
"yo": "Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ní àwọn òfin àti àbádòfin tí ó fún ọmọ ènìyàn ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ."
} |
{
"en": "In Nigeria, for example, the Freedom of Information Act grants citizens the right to demand information from any government agency.",
"yo": "Ní Nàìjíríà, fún àpẹẹrẹ, Àbádòfin Òmìnira Ọ̀rọ̀ fún ọmọ ìlú ní òmìnira láti béèrè fún ìwífun lọ́wọ́ àjọ ìjọba."
} |
{
"en": "Section 22 of the 1999 Constitution provides for freedom of the press and Section 39 maintains that \"every person shall be entitled to freedom of expression, including the freedom to hold and to receive and impart ideas and information without interference...\"",
"yo": "Abala 22 ìwé òfin ọdún 1999 pèsè fún ẹ̀tọ́ òmìnira ìròyìn àti Abala 39 fi lélẹ̀ wípé \"gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títí kan òmìnira láti gbá ìròyìn mú àti gba ọgbọ́n àti ìwífun láì sí ìdíwọ́...\""
} |
{
"en": "Yet, Nigeria has issued other laws that authorities use to deny these aforementioned rights.",
"yo": "Síbẹ̀, Nàìjíríà tí tẹ àwọn òfin kan tí ó tẹ orí àwọn ẹ̀tọ́ òkè yìí bọlẹ̀."
} |
{
"en": "Section 24 of Nigeria’s Cybercrime Act criminalises \"anyone who spreads messages he knows to be false, for the purpose of causing annoyance, inconvenience, danger, obstruction, insult, injury, criminal intimidation, enmity, hatred, ill will or needless anxiety to another or causes such a message to be sent.\"",
"yo": "Abala 24 Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára fi ẹ̀sùn kan \"ẹnikẹ́ni tí ó bá tan iṣẹ́-ìjẹ́ tí kò ní òótọ́ kan nínú, tí ó lè fa ìbínú, ìnira, ewu, ìdíwọ́, àfojúdi, ìdáyàfò ọ̀daràn, ọ̀tá, ìkórìíra, tàbí ìbínú láì ní ìdí sí ẹlòmíràn ká tàbí fa kí a fi irúfẹ́ iṣẹ́-ìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́.\""
} |
{
"en": "Making laws with ambiguous and subjective terms like \"inconvenience\" or \"insult\" calls for concern.",
"yo": "Ìṣòfin àìdájú àti àwọn gbólóhùn bíi \"ìnira\" tàbí \"ìwọ̀sí\" jẹ́ nǹkan tí a ní láti mójútó."
} |
{
"en": "Governments and their agents often use this as a cover to suppress freedom of expression.",
"yo": "Ìjọba àti àwọn àjọ rẹ̀ máa ń sábà fi èyí ṣe bójúbójú fún ìtẹríbọlẹ̀ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ."
} |
{
"en": "Who determines the definition of an insult?",
"yo": "Ta ni ẹni tí ó ń sọ bóyá ọ̀rọ̀ kan jẹ́ àfojúdi?"
} |
{
"en": "Should public officials expect to develop a thick skin?",
"yo": "Ǹjẹ́ ó yẹ kí òṣìṣẹ́ ìjọba ó ṣe ìmúdàgbà àwọ̀-ara tí ó ní ipọn?"
} |
{
"en": "In many parts of the world, citizens have the right to criticise public officials.",
"yo": "Ní àgbáyé, ọmọ-ìlú ní ẹ̀tọ́ láti wá àìṣedéédé aláṣẹ ìjọba."
} |
{
"en": "Why don't Africans have the right to offend as an essential part of free expression?",
"yo": "Kí ló dé tí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tí ó ṣe pàtàkì nínú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ?"
} |
{
"en": "In 2017 and 2016, Nigerian online journalists and bloggers Abubakar Sidiq Usman and Kemi Olunloyo were each booked on spurious charges of cyber-stalking in connection with journalistic investigations on the basis of the Cybercrime Act.",
"yo": "Ní ọdún 2017 àti 2016, oníròyìn orí-ayélujára ọmọ bíbí ìlú Nàìjíríà àti akọbúlọ́ọ̀gù Abubakar Sidiq Usman àti Kẹ́mi Olúnlọ́yọ̀ọ́ tí ta ẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí òfin nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́ ìkóròyìnjọ lóríi Òfin Ẹ̀ṣẹ̀ orí-ayélujára."
} |
{
"en": "Don’t suffer in silence — keep talking",
"yo": "Má jìyà nínú Ìdáké̩ró̩ró̩ — máa wí lọ"
} |
{
"en": "The very existence of these legal challenges tells citizens that their voices matter.",
"yo": "Ìwà tí ó jẹ́ gbòògì àwọn ìpèníjà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ti òfin ń sọ fún ọmọ-ìlú pé ohùn-un wọn ṣe kókó."
} |
{
"en": "From Tanzania’s prohibition on spreading \"false, deceptive, misleading or inaccurate\" information online to Uganda’s tax on social media that is intended to curb \"gossip\", the noise made on digital platforms scares oppressive regimes. In some cases, it may even lead to them to rescind their actions.",
"yo": "Kí a mú un láti Ìdádúró Tanzania tí ó dá lóríi ìtànká \"ìròyìn irọ́, ìtànjẹ, tàbí ìròyìn tí ò pé ojú òṣùwọ̀n\" lórí ayélujára títí kan owó-orí Uganda fún ìlò ẹ̀rọ-alátagbà fún ìgbógunti \"àhesọ\", ariwo orí ẹ̀rọ-ayárabíaṣá ń já àwọn ìjọba aninilára láyà. Ní ìgbà mìíràn, ó máa mú wọn pa àwọn ìwàa wọn tì."
} |
{
"en": "The experience of the Zone9 bloggers of Ethiopia provides a powerful example.",
"yo": "Ìrírí akọbúlọ́ọ̀gù Zone9 ìlú Ethiopia jẹ́ àpẹẹrẹ."
} |
{
"en": "In 2014, nine Ethiopian writers were jailed and tortured over a collective blogging project in which they wrote about human rights violations by Ethiopia’s former government, daring to speak truth to power.",
"yo": "Ní ọdún 2014, àwọn òǹkọ̀wé ọmọ bíbí Ethiopia mẹ́sàn-án lọ sí ẹ̀wọ̀n àti jìyà oró látàrí iṣẹ́ àjọṣepọ̀ tí wọ́n jọ kọ nípa ìtẹsẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ẹ̀tọ́ ọmọ-ènìyàn ìjọba àná ìlú Ethiopia, kí òótọ́ ó di mímọ̀."
} |
{
"en": "The state labeled the group \"terrorists\" for their online activity and incarcerated them for almost 18 months.",
"yo": "Ìjọba pe ẹgbẹ́ yìí ni \"afẹ̀míṣòfò\" nítorí àtẹ̀jáde orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn a sì ti wọ́n mọ́lé fún oṣù 18."
} |
{
"en": "Zone9 members Mahlet (left) and Zelalem (right) rejoiced at the release of Befeqadu Hailu (second from left, in scarf) in October 2015.",
"yo": "Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Zone9 Mahlet (òsì) àti Zelalem (ọ̀tún) ń dunnú fún ìdásílẹ̀lẹ́wọ̀n Befeqadu Hailu (ẹnìkejì láti ọwọ́ òsì, pẹ̀lú sícáàfù) ní oṣù kẹwàá ọdún 2015."
} |
{
"en": "Photo shared on Twitter by Zelalem Kiberet.",
"yo": "Orí Twitter ni Zelalem Kiberet ti pín àwòrán yìí."
} |
{
"en": "Six members of the now liberated group made their premier international engagement in Ghana during FIFA conference: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, and Abel Wabella were all in attendance.",
"yo": "Àwọn mẹ́fà lára àwọn ẹgbẹ́ náà tí ó ti gba òmìnira báyìí ṣe ìtàkùrọ̀sọ àgbáyé àkọ́kọ́ ní ìlú Ghana ní àsìkò àpérò FIFA: Atnaf Berhane, Befeqadu Hailu Techane, Zelalem Kibret, Natnael Feleke Aberra, àti Abel Wabella náà wá sí àpérò."
} |