translation
dict |
---|
{
"en": "Since being detained, Andrzej has been held in solitary confinement.",
"yo": "Àtìmọ́lé ni Andrzej wà látìgbà tí wọ́n ti mú un."
} |
{
"en": "From 6:00 a.m. to 9:00 p.m., he is not permitted to lie down.",
"yo": "Orí ìdúró ló máa ń wà láti aago mẹ́fà àárọ̀ títí di aago mẹ́sàn-án alẹ́."
} |
{
"en": "He is only allowed to take a shower with hot water once a week for 15 minutes.",
"yo": "Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ni wọ́n fàyè gbà á láti fi omi tó ń lọ́ wọ́ọ́rọ́ wẹ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún."
} |
{
"en": "Andrzej’s wife, Anna, has not been allowed to visit Andrzej for the ten months he has been in detention.",
"yo": "Fún oṣù mẹ́wàá tó fi wà láhàámọ́, wọn ò jẹ́ kí Anna ìyàwó rẹ̀ rí i."
} |
{
"en": "They can only communicate by mail.",
"yo": "Lẹ́tà ni wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀."
} |
{
"en": "She has submitted numerous requests to visit Andrzej, but each time she has been denied.",
"yo": "Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Anna ti kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n gbà á láyè láti rí ọkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn ò dá a lóhùn."
} |
{
"en": "As previously reported, Andrzej was arrested after local police and masked special forces raided his home and 18 others in Kirov.",
"yo": "Bá a ṣe sọ ṣáájú, ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun tó fi nǹkan bojú fipá ya wọ ilé Andrzej àtàwọn méjìdínlógún (18) míì nílùú Kirov ni wọ́n mú un."
} |
{
"en": "A criminal case was opened against Andrzej for singing Kingdom songs and studying religious literature.",
"yo": "Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn àn torí ó ń kọrin ìjọba Ọlọ́run, ó sì tún ń ka ìtẹ̀jáde wa."
} |
{
"en": "Along with Andrzej, four other brothers from Kirov (44-year-old Maksim Khalturin, 66-year-old Vladimir Korobeynikov, 26-year-old Andrey Suvorkov, and 41-year-old Evgeniy Suvorkov) were arrested last year and placed in pretrial detention.",
"yo": "Lọ́dún tó kọjá, wọ́n mú Andrzej àtàwọn arákùnrin mẹ́rin míì nílùú Kirov (ìyẹn, Maksim Khalturin, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì (44), Vladimir Korobeynikov, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin (66), Andrey Suvorkov, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) àti Evgeniy Suvorkov, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) sátìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn."
} |
{
"en": "They have since been placed under house arrest.",
"yo": "Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ní wọn ò gbọdọ̀ jáde nílé."
} |
{
"en": "Andrzej’s case, together with these four, is pending with the European Court of Human Rights.",
"yo": "Ní báyìí, ẹjọ́ Andrzej àti tàwọn arákùnrin mẹ́rin yẹn ti wà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù."
} |
{
"en": "This year, Russian authorities have opened criminal cases against seven more brothers from Kirov—the oldest is 70-year-old Yevgeniy Udintsev.",
"yo": "Lọ́dún yìí, ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún ti fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn arákùnrin méje míì ní Kirov, Yevgeniy Udintsev tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún (70) ló dàgbà jù."
} |
{
"en": "A total of 12 Jehovah’s Witnesses in Kirov are now facing criminal charges for practicing their faith.",
"yo": "Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn ní Kirov nítorí ìgbàgbọ́ wọn ti di méjìlá (12)."
} |
{
"en": "Regarding Andrzej, Anna, and the rest of our dear Russian brothers and sisters, may we never forget the inspired reminder: “Keep in mind those in prison, as though you were imprisoned with them, and those being mistreated, since you yourselves also are in the body.”—Hebrews 13:3.\"",
"yo": "Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí Andrzej, Anna àtàwọn ará wa ọwọ̀n tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ń rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, tó sọ pé: “Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n, bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n àti àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ, torí pé ẹ̀yin fúnra yín náà wà nínú ara.”—Hébérù 13:3.\""
} |
{
"en": "On the morning of June 7, 2018, 10 of the wives of the 17 imprisoned Witnesses in Russia sent an open letter to Mikhail Fedotov, adviser to President Putin and chairman of the Presidential Council for Civil Society and Human Rights.",
"yo": "Láàárọ̀ June 7, 2018, mẹ́wàá nínú ìyàwó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàdínlógún (17) tó wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí Mikhail Fedotov, tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn Ààrẹ Putin àti alága Ìgbìmọ̀ Ààrẹ Lórí Ọ̀rọ̀ Aráàlú àti Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn."
} |
{
"en": "\"On February 25, 2019, an application for urgent measures was filed with the European Court of Human Rights (ECHR) on behalf of Brother Sergey Loginov, one of the seven brothers who was tortured by officials in the western Siberian city of Surgut.",
"yo": "\"Ní February 25, 2019 a kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR), pé kí wọ́n tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ Arákùnrin Sergey Loginov, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin méje táwọn aláṣẹ fìyà jẹ ní ìlú Surgurt tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sàìbéríà."
} |
{
"en": "The other six brothers who were tortured have been released, but Brother Loginov has been in pretrial detention since his arrest and does not have access to adequate medical care for his injuries.",
"yo": "Wọ́n ti tú àwọn arákùnrin mẹ́fà tó kù sílẹ̀, àmọ́ Arákùnrin Loginov ṣì wà látìmọ́lé látìgbà tí wọ́n ti mú un, bẹ́ẹ̀, wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kó lọ tọ́jú àwọn ọgbẹ́ tó wà lára rẹ̀."
} |
{
"en": "On February 26, just a day after the application was filed, the ECHR responded with a favorable ruling.",
"yo": "Ní February 26, ìyẹn ọjọ́ kan lẹ́yìn tá a kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ ECHR, wọ́n fèsì, èsì náà sì dáa gan-an."
} |
{
"en": "The Court granted the request, ordering Russia to “immediately” have Brother Loginov examined by a team of independent doctors to determine the extent of the “physical and psychological” harm he suffered and whether his health allows for continued detention.",
"yo": "Ilé Ẹjọ́ fọwọ́ sí ohun tá a béèrè, wọ́n sì pàṣẹ pé “ní kíá” kí ìjọba Rọ́ṣíà jẹ́ kí àwùjọ àwọn dókítà tó ń dá ṣiṣẹ́ ṣàyẹ̀wò Arákùnrin Loginov kí wọ́n lè mọ bí àkóbá tí ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ṣe pọ̀ tó “nínú àgọ́ ara rẹ̀ àti nínú ọpọlọ rẹ̀” àti bóyá ara rẹ̀ ṣì le tó láti wà látìmọ́lé."
} |
{
"en": "The Russian government has until March 11, 2019, to respond.",
"yo": "Títí di March 11, 2019, ìjọba Rọ́ṣíà ò ṣe nǹkan kan."
} |
{
"en": "The ECHR grants such requests only in exceptional circumstances, when an individual is at risk of imminent and irreparable harm.",
"yo": "Ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni Ilé Ẹjọ́ ECHR máa ń ṣe irú ìdájọ́ kíákíá yìí, ó sì máa ń jẹ́ tí ẹ̀mí ẹni tọ́rọ̀ kàn bá wà nínú ewu, tí nǹkan sì lè bà jẹ́ kọjá àtúnṣe."
} |
{
"en": "It is therefore encouraging to note that the ECHR took this step and so quickly—just a day after the application was filed.",
"yo": "Ó dùn mọ́ni nínú pé Ilé Ẹjọ́ ECHR tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ yìí láàárín ọjọ́ kan péré tá a kọ̀wé sí wọn."
} |
{
"en": "The ECHR has indicated that it will closely monitor the abuse suffered by our brothers.",
"yo": "Ilé Ẹjọ́ ECHR sì sọ pé wọ́n máa rí i dájú pé àwọn fojú sí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ará wa."
} |
{
"en": "Currently, 19 Witnesses are facing criminal charges in Surgut, 3 of whom are being held in pretrial detention.",
"yo": "Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Ẹlẹ́rìí mọ́kàndínlógún (19) ló ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n ní ìlú Surgut, mẹ́ta lára wọn sì ti wà látìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn."
} |
{
"en": "As we continue to supplicate Jehovah in behalf of our brothers, may we keep firmly in mind the reassuring words of Jeremiah: “Blessed is the man who puts his trust in Jehovah, whose confidence is in Jehovah.”—Jeremiah 17:7.\"",
"yo": "Bá a ṣe ń bá àwọn ará wa bẹ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tí Jeremáyà sọ sọ́kàn pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”—Jeremáyà 17:7.\""
} |
{
"en": "\"On June 6, 2019, two weeks after Brother Dennis Christensen lost his appeal, Russian authorities transferred him from his pretrial detention cell in Oryol to prison—Penal Colony No. 3 in the city of Lgov.",
"yo": "\"Ní June 6, 2019, ìyẹn ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí Arákùnrin Dennis Christensen pàdánù ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè, àwọn alákòóso Rọ́ṣíà gbé e láti yàrá ìtìmọ́lé tó wà ṣáájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ní Oryol, lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní àdádó, ìyẹn Penal Colony No. 3 nílùú Lgov."
} |
{
"en": "Lgov is approximately 200 kilometers (124 mi) away from Dennis’ family and friends back home in Oryol.",
"yo": "Ìlú Lgov jìn tó igba (200) kìlómítà sí ibi tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Dennis ń gbé ní Oryol."
} |
{
"en": "When Dennis first arrived at the prison, he was subjected to insults and efforts to break his resolve.",
"yo": "Nígbà tí Dennis kọ́kọ́ dé ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n sì gbìyànjú láti mú kó sẹ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀."
} |
{
"en": "Yet, Dennis has relied heavily on Jehovah and has shown himself to be strong and fearless.—1 Peter 5:10.",
"yo": "Àmọ́, ṣe ni Dennis gbára lé Jèhófà pátápátá, ó sì fi hàn pé òun jẹ́ alágbára àti onígboyà.—1 Pétérù 5:10."
} |
{
"en": "In Finland (left to right): Mark Sanderson of the Governing Body, Irina Christensen, and Tommi Kauko from Finland",
"yo": "Ní Finland (láti apá òsì sí apá ọ̀tún): Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, Irina Christensen, àti Tommi Kauko láti Finland"
} |
{
"en": "Since Dennis’ arrest and detention, the brothers have offered loving support and care for his wife, Irina.",
"yo": "Látìgbà tí wọ́n ti ti Dennis mọ́lé ni àwọn ara ti ń ti ìyàwó ẹ̀, Irina, lẹ́yìn tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ bójú tó o."
} |
{
"en": "In June, Brother Mark Sanderson of the Governing Body and other responsible brothers were able to meet with Irina in Finland for an encouraging visit.",
"yo": "Ní June, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti àwọn arákùnrin míì tó ń mú ipò iwájú ṣètò bí wọ́n ṣe pàdé Irina ní Finland ki wọ́n lè fún un níṣìírí."
} |
{
"en": "Dennis has been in the penal colony now for over a month.",
"yo": "Ó ti tó oṣù kan báyìí tí Dennis tí wà lẹ́wọ̀n yìí."
} |
{
"en": "Irina was recently given permission to speak with him, once a day, over the telephone.",
"yo": "Láìpẹ́ yìí ni wọ́n gba Irina láàyè láti máa bá Dennis sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ lórí fóònù."
} |
{
"en": "Approval has also been granted for her to visit him at the prison.",
"yo": "Wọ́n tún ti fọwọ́ sí i pé kó máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Dennis ní ọgbà ẹ̀wọ̀n."
} |
{
"en": "Irina rereading encouraging letters from Dennis",
"yo": "Irina ń tún àwọn lẹ́tà tó ń fúnni níṣìírí tí Dennis kọ sí i kà"
} |
{
"en": "With all that Dennis and Irina have endured over the past two years since his arrest and imprisonment, they remain steadfast and joyful.",
"yo": "Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Dennis àti Irina ti fara dà fún ọdún méjì sẹ́yìn, ìyẹn láti igba tí wọ́n ti mú u tí wọn sì tì í mọ́lé, síbẹ̀ wọ́n dúró láìyẹsẹ̀, wọ́n sì ń láyọ̀."
} |
{
"en": "According to Irina, the weekly letters from Dennis have been especially uplifting.",
"yo": "Irina sọ pé àwọn lẹ́tà tí Dennis ń kọ sí òun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa ń gbé òun ro gan an ni."
} |
{
"en": "In one of her favorite letters from him, Dennis wrote: “Staying positive is a key to success and we have so many reasons to be joyful.”",
"yo": "Ọ̀kan wà lára àwọn lẹ́tà yẹn ti Irina fẹ́ràn gan an, Dennis kọ̀wé pé: “A máa ṣàṣeyọrí tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, bẹ́ẹ̀ sì rèé àìmọye nǹkan tó ń fún wa láyọ̀ la ní.”"
} |
{
"en": "He concluded: “Upholding Jehovah’s sovereignty is the reason for our existence.",
"yo": "Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí: “Torí ká lè fi hàn pé Jèhófà la fara mọ́ pé kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ la ṣe wà láyé."
} |
{
"en": "I know that our journey is a long one and we have not won the victory—not yet.",
"yo": "Mo mọ̀ pé ọnà wa ṣì jìn, a ò sì tíì ṣẹ́gun."
} |
{
"en": "But we will eventually come off victorious.",
"yo": "Àmọ́, mo mọ̀ pé bó pẹ́ bóyá, à máa ṣẹ́gun."
} |
{
"en": "Of that I am 100 percent certain.”",
"yo": "Ìyẹn dá mi lójú hán-ún hán-ún.”"
} |
{
"en": "On July 21, at the international convention in Denmark, Brother Lett of the Governing Body read a message from Dennis.",
"yo": "Ní July 21, ní àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní Denmark, Arákùnrin Lett tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ka lẹ́tà kan tí Dennis kọ."
} |
{
"en": "Which said, in part: “I wish I could be gathered with you, but this is currently not possible since I have not yet completed my present assignment.",
"yo": "Apá kan nínú lẹ́tà náà sọ pé: “Ó wù mí kí n wà pẹ̀lú yín ní àpéjọ yìí, ṣùgbọ́n ìyẹn ò ṣeéṣe báyìí torí pé mi ò tíì parí iṣẹ́ tí a yàn fún mi."
} |
{
"en": "But it will be possible in the future, and I am looking forward to it.”",
"yo": "Àmọ́, ó máa ṣeéṣe lọ́jọ́ iwájú, mo sì ń wọ̀nà fún un.”"
} |
{
"en": "While under arrest in Rome, Paul wrote: “I thank my God always when I remember you in every supplication of mine for all of you.",
"yo": "Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé ní Róòmù, ó kọ̀wé pé: “Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi lórí gbogbo yín."
} |
{
"en": "I offer each supplication with joy, . . . I have you in my heart, you who are sharers with me in the undeserved kindness both in my prison bonds and in the defending and legally establishing of the good news.”—Philippians 1:3, 4, 7.\"",
"yo": "Inú mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀,. . . ọ̀rọ̀ yín ń jẹ mí lọ́kàn, ẹ sì jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi àti nínú bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.”—Fílípì 1:3, 4, 7.\""
} |
{
"en": "\"Brother Arkadya Akopyan will have his final day in court on December 21, 2018.",
"yo": "\"December 21, 2018 ni Arákùnrin Arkadya Akopyan, máa fara hàn kẹ́yìn nílé ẹjọ́."
} |
{
"en": "The brother 70-year-old retired tailor is in the Russian Republic of Kabardino-Balkaria.",
"yo": "Apá kan nílẹ̀ Rọ́ṣíà tí wọ́n ń pè ní Kabardino-Balkaria ni arákùnrin tó jẹ́ ẹni àádọ́rin (70) ọdún yìí ti wá, ó sì ti fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́ télọ̀."
} |
{
"en": "He has been on trial in the Prohladniy District Court for over a year, defending himself against the accusation that he distributed “extremist” literature and ‘incited religious hatred’ during a Bible discourse at a Kingdom Hall.",
"yo": "Ó ti lé lọ́dún kan tí ẹjọ́ rẹ̀ ti wà ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Prohladniy, tó ń gbèjà ara rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń pín ìwé àwọn tí wọ́n kà sí agbawèrèmẹ́sìn àti pé ó ń ṣagbátẹrù ìkórìíra ẹ̀sìn nínú àsọyé kan tó sọ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba."
} |
{
"en": "It is uncertain whether the judge will issue a verdict on December 21.",
"yo": "Kò dájú pé adájọ́ máa dá ẹjọ́ rẹ̀ ní December 21."
} |
{
"en": "However, if convicted, Brother Akopyan faces a heavy fine or up to four years in prison.",
"yo": "Àmọ́ tí wọ́n bá dá Arákùnrin Akopyan lẹ́bi, wọ́n lè bu owó ìtanràn tó pọ̀ lé e tàbí kí wọ́n rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin."
} |
{
"en": "Brother Akopyan is one of over 100 other Jehovah’s Witnesses in Russia facing criminal charges for their faith.",
"yo": "Arákùnrin Akopyan wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) tí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ní Rọ́ṣíà nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́."
} |
{
"en": "Consequently, we pray that all of our brothers and sisters who are standing firm in the faith continue to have the peace that only God can give.—Ephesians 6:11-14, 23.\"",
"yo": "Àdúrà wa ni pé kí gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn ò yẹsẹ̀ máa ní àlàáfíà tí Ọlọ́run nìkan lè fúnni.—Éfésù 6:11-14, 23.\""
} |
{
"en": "\"Early in the morning of April 10, 2018, investigators and special police forces, some wearing masks and carrying automatic weapons, raided and searched the homes of several Witnesses in Ufa, the capital city of Bashkortostan, Russia.",
"yo": "\"Láàárọ̀ kùtù April 10, ọdún 2018, àwọn tó ń ṣèwádìí àtàwọn ọlọ́pàá àrà ọ̀tọ̀, tí lára wọn fi nǹkan bojú tí wọ́n sì gbé ìbọn arọ̀jò ọta, já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú Ufa, olú ìlú Bashkortostan, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n tú gbogbo ilé wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́."
} |
{
"en": "Brother Anatoliy (Tolya) Vilitkevich was arrested, and the authorities are holding him in pretrial detention.",
"yo": "Wọ́n mú Arákùnrin Anatoliy (Tolya) Vilitkevich, àwọn aláṣẹ sì fì í sí àtìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀."
} |
{
"en": "Five sisters from Ufa, including Tolya’s wife, Alyona, recount how the raids have affected them.",
"yo": "Àwọn arábìnrin márùn-ún láti ìlú Ufa, tó fi mọ́ Alyona, ìyàwó Tolya ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n já wọlé wọn."
} |
{
"en": "Sorry, the media player failed to load.",
"yo": "Máà bínú, ètò tó o fi ń wo fídíò kò ṣiṣẹ́."
} |
{
"en": "Download This Video\"",
"yo": "Wa Fídíò Yìí Jáde\""
} |
{
"en": "\"On July 2, 2019, a court in Krasnoyarsk, Russia, ruled to release Brother Andrey Stupnikov from house arrest.",
"yo": "\"Ní July 2, 2019, ilé ẹjọ́ kan ní ìlú Krasnoyarsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dájọ́ pé kí wọ́n fi Arákùnrin Andrey Stupnikov sílẹ̀, kí wọ́n má ṣe sé e mọ́lé mọ́."
} |
{
"en": "Although he is no longer under house arrest, his criminal case remains open.",
"yo": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sé e mọ́lé mọ́, àwọn aláṣẹ ṣì kà á sí ọ̀daràn, wọ́n sì ń bá ìwádìí lọ lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀."
} |
{
"en": "Brother Andrey Stupnikov",
"yo": "Arákùnrin Andrey Stupnikov"
} |
{
"en": "On July 3, 2018, the Stupnikovs were checking in for an early morning flight at the Krasnoyarsk International Airport.",
"yo": "Ní July 3, 2018, bí ìdílé Stupnikov ṣe fẹ́ wọkọ̀ òfúrufú láàárọ̀ kùtù ní Pápákọ̀ Òfúrufú Krasnoyarsk, ní Yemelyanovo, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà."
} |
{
"en": "Two Federal Security Service agents approached and arrested Brother Stupnikov.",
"yo": "Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbọ̀ ìjọba méjì fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Stupnikov."
} |
{
"en": "He then spent eight months in pretrial detention before being moved to house arrest at the end of February 2019.",
"yo": "Odindi oṣù mẹ́jọ ló lò ní ẹ̀wọ̀n láìjẹ́ pé wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ rárá, lẹ́yìn náà ni wọ́n sé e mọ́lé láti ìparí oṣù February, 2019."
} |
{
"en": "According to Brother Stupnikov, he has learned much about himself and his relationship with Jehovah over the past year.",
"yo": "Bí arákùnrin Stupnikov ṣe sọ, ohun tójú ẹ̀ rí láàárín ọdún kan yìí ti jẹ́ kó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ara ẹ̀ àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà."
} |
{
"en": "He states: “[Olga and I] have been Witnesses for many years, but we have never had such a close relationship with Jehovah!",
"yo": "Ó sọ pé: “[Èmi àti Olga] ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àmọ́ a ò sún mọ́ Jèhófà tó báyìí rí láyé wa!"
} |
{
"en": "In the most difficult of times, I have felt, and continue to feel, the presence and support of our Father.",
"yo": "Láwọn ìgbà tí nǹkan nira gan-an, mo máa ń rí bí Bàbá wa ọ̀run ṣe ń tù mí nínú tó sì ń ràn mí lọ́wọ́."
} |
{
"en": "It amazes me just how close he has been to me and how quickly he has answered my prayers!”",
"yo": "Ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí bí Jèhófà ṣe ń dúró tì mí tó sì máa ń tètè dáhùn àdúrà mi!”"
} |
{
"en": "Brother Stupnikov concludes: “More than ever before, I am convinced that my Father knows and understands my feelings.",
"yo": "Arákùnrin Stupnikov parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó ti wá dá mi lójú pé Jèhófà Bàbá mi lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára mi torí pé ó mọ̀ mí dáadáa."
} |
{
"en": "This personal experience helps me to trust in him more fully and to not worry excessively about persecution.",
"yo": "Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí ti jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n gbára lé Jèhófà pátápátá, kí n má sì máa da ara mi láàmú ju bó ṣe yẹ lọ nítorí inúnibíni."
} |
{
"en": "It is much more frightening to lose this close relationship with Jehovah.",
"yo": "Mo tún rí i pé èèyàn máa kábàámọ̀ tó bá pàdánù irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà."
} |
{
"en": "I am convinced that with him we can overcome anything.”",
"yo": "Ó dá mi lójú pé tí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, kò síṣòro tá ò ní lè borí.”"
} |
{
"en": "The growing list of criminal cases against our brothers and sisters in Russia has reached 217 as of July 1.",
"yo": "Láti July 1, ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ti fi kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti tó igba ó lé mẹ́tàdínlógún (217)."
} |
{
"en": "In a few instances, Russian authorities have reduced the restrictions on some of our brothers.",
"yo": "Láwọn ipò kan, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti dín ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ara wa kan kù."
} |
{
"en": "However, we do not put our trust in human courts or officials—our trust remains in Jehovah.",
"yo": "Àmọ́, kì í ṣe àwọn aláṣẹ ilé ẹjọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé, Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé."
} |
{
"en": "We pray that Jehovah continues to strengthen and shield all of our fellow worshippers in Russia.—Psalm 28:7.\"",
"yo": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa fún àwọn ará wa tó wà ní Rọ́ṣíà lágbára, kó sì máa dáàbò bò wọ́n.—Sáàmù 28:7.\""
} |
{
"en": "\"On Thursday, July 4, 2019, the Ordzhonikidzevskiy District Court in the Russian city of Perm’ announced the conviction of Brother Aleksandr Solovyev and fined him 300,000 rubles ($4,731 U.S.).",
"yo": "\"Ní Thursday, July 4, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ordzhonikidzevskiy ní agbègbè Perm’ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kéde pé Arákùnrin Aleksandr Solovyev jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì ní kó san ìtanràn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (4,731) owó dọ́là."
} |
{
"en": "Brother Solovyev was arrested on the evening of May 22, 2018, at a railway station, as he was arriving home from a trip abroad with his wife, Anna.",
"yo": "Ìrọ̀lẹ́ May 22, 2018 ni wọ́n fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Solovyev ní ibùdókọ̀ ojú irin nígbà tí òun àti Anna ìyàwó rẹ̀ ń bọ̀ láti ìrìn-àjò tí wọ́n lọ lórílẹ̀-èdè míì."
} |
{
"en": "Police officers handcuffed Brother Solovyev and took him to a temporary detention center.",
"yo": "Àwọn ọlọ́pàá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sọ́wọ́ Arákùnrin Solovyev, wọ́n sì fi í sátìmọ́lé fúngbà díẹ̀."
} |
{
"en": "Sister Solovyev was also taken away by the police but in a separate vehicle from her husband.",
"yo": "Àwọn ọlọ́pàá tún mú Arábìnrin Solovyev, àmọ́ ọkọ̀ tí wọ́n fi gbé e yàtọ̀ sí ti ọkọ̀ ẹ̀."
} |
{
"en": "Officers searched their apartment all night—seizing photographs, electronic devices, and a collection of Bibles.",
"yo": "Àwọn ọlọ́pàá tú ilé wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ní gbogbo òru, wọ́n sì kó àwọn fọ́tò wọn, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti oríṣiríṣi Bíbélì."
} |
{
"en": "After some questioning, Sister Solovyev was released and not charged.",
"yo": "Wọ́n da ìbéèrè bo Arábìnrin Solovyev, lẹ́yìn náà wọ́n tú u sílẹ̀, wọn ò sì fẹ̀sùn kàn án."
} |
{
"en": "However, a criminal case was initiated against Brother Solovyev, and on May 24, he was placed under house arrest until November 19, 2018.",
"yo": "Àmọ́, wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Solovyev, nígbà tó sì di May 24, wọ́n sé e mọ́lé títí di November 19, 2018."
} |
{
"en": "While awaiting trial, he has been required to comply with restrictions on his activities.",
"yo": "Kó tó dìgbà tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀, wọ́n ò fún un lómìnira láti jáde bó ṣe fẹ́."
} |
{
"en": "Attorneys for Brother Solovyev will appeal the conviction.",
"yo": "Agbẹjọ́rò Arákùnrin Solovyev máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un."
} |
{
"en": "They have also filed an application with the United Nations Working Group Against Arbitrary Detention.",
"yo": "Wọ́n tún ti kọ̀wé sí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Tó Ń Gbógun Ti Fífini Sátìmọ́lé Lọ́nà Tí Kò Bójú Mu."
} |
{
"en": "As persecution increases in places like Russia, we are “in no way being frightened” by our opponents.",
"yo": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti láwọn orílẹ̀-èdè míì ń le sí i, a ò ní jẹ́ káwọn alátakò yìí “kó jìnnìjìnnì bá wa lọ́nàkọnà.”"
} |
{
"en": "We trust that Jehovah will continue to give all of us what we need to endure until his great day of salvation comes.—Philippians 1:28\"",
"yo": "Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fara dà á títí táyé tuntun tá à ń retí fi máa dé.—Fílípì 1:28\""
} |
{
"en": "\"During the month of October 2018, local and federal police raided more than 30 homes throughout western Russia.",
"yo": "\"Nínú oṣù October 2018, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé tó ju ọgbọ̀n (30) lọ káàkiri ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà."
} |
{
"en": "Six brothers and two sisters were arrested and sentenced to pretrial detention for so-called extremist activity.",
"yo": "Wọ́n mú arákùnrin mẹ́fà àti arábìnrin méjì, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí ilé ẹjọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ wọn lórí ẹ̀sùn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n."
} |
{
"en": "Consequently, there are now 25 brothers and sisters unjustly imprisoned, and 18 others are under house arrest.",
"yo": "Ní báyìí, àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n ti rán lọ sẹ́wọ̀n láìtọ́ jẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), wọ́n sì sọ fún àwọn méjìdínlógún (18) míì pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé."
} |
{
"en": "October 7, Sychyovka, Smolensk Region—Local police and masked special forces searched four homes and arrested two sisters, 43-year-old Nataliya Sorokina and 41-year-old Mariya Troshina.",
"yo": "October 7, ní Sychyovka, Àgbègbè Smolensk—Àwọn ọlọ́pàá àdúgbò àtàwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú lọ tú ilé mẹ́rin, wọ́n sì mú arábìnrin méjì, ìyẹn Nataliya Sorokina tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì (43) àti Mariya Troshina tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41)."
} |
{
"en": "Two days after their arrest, the Leninsky District Court sentenced our sisters to pretrial detention through November 19, 2018.",
"yo": "Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wọ́n mú wọn, Ilé Ẹjọ́ Leninsky rán àwọn arábìnrin wa lọ sí àtìmọ́lé títí di November 19, 2018."
} |
{
"en": "Then, on November 16, 2018, the Leninsky District Court extended the sisters’ pretrial detention for an additional three months, that is, until February 19, 2019.",
"yo": "Àmọ́ nígbà tó di November 16, 2018, Ilé Ẹjọ́ Leninsky fi oṣù mẹ́ta kún ọjọ́ táwọn arábìnrin wa máa lò látìmọ́lé, tó fi hàn pé wọ́n á wà níbẹ̀ títí di February 19, 2019 nìyẹn."
} |
{
"en": "October 9, Kirov, Kirov Region—At least 19 homes were raided.",
"yo": "October 9, ní Kirov, Àgbègbè Kirov—Ó kéré tán, ilé mọ́kàndínlógún (19) ni wọ́n ya wọ̀."
} |
{
"en": "Five congregation elders were arrested and later sentenced to pretrial detention.",
"yo": "Wọ́n mú àwọn alàgbà ìjọ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí àtìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn."
} |
{
"en": "Four of the brothers (Maksim Khalturin, Vladimir Korobeynikov, Andrey Suvorkov, and Evgeniy Suvorkov) are Russian nationals, and one, Andrzej Oniszczuk, is a Polish citizen.",
"yo": "Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ni mẹ́rin lára wọn (ìyẹn Maksim Khalturin, Vladimir Korobeynikov, Andrey Suvorkov àti Evgeniy Suvorkov) ẹnì kan tó kù, ìyẹn Andrzej Oniszczuk, jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland."
} |
{
"en": "Brother Oniszczuk is the second foreigner, after Dennis Christensen from Denmark, to be unjustly detained in Russia for his Christian beliefs.",
"yo": "Yàtọ̀ sí Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark, Arákùnrin Oniszczuk ló máa jẹ́ ẹnì kejì tó wá láti orílẹ̀-èdè míì táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà máa mú sílẹ̀ ní Rọ́ṣíà torí ohun tó gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni."
} |